Naija we hail oooo Una no dey fail oooo even when the country they wail lli oooo

Sunday, March 26, 2017

Ni odun yii 2017

NI ODUN 2017 adura MI si o ni wipe:

🏾A* - Alaafia ni fun ọ.

🏾B* - Buburu kan ki yio
ṣsubú lu ọ.

🏾D* - Dugbẹdugbẹ
ibanujẹ ko ni ja le ọ
l'ori.

🏾E* - Ebi ò ni pa ọ nibi ti
ọdún ku si yi.

🏾E* - Ẹkún, asun'da ko ni jẹ
tirẹ.

🏾F* - Funfun aye rẹ ko ni
d'ibajẹ.

🏾G* - Gunnugun ki ku
l'ewe, wa d'agba
d'arugbo.

🏾GB* - Gbogbo idawole
rẹ a yọrí si rere.

🏾H* - Hausa, Yoruba, Ibo,
gbogbo ẹya ati
eniyan kaakiri
agbaye ni yio kọju
si ọ ṣe ọ loore.

🏾I* - Iwaju, iwaju l'ọpa ẹbiti
rẹ yio ma re si.

🏾J* - Jijade rẹ, wiwole rẹ,
ò ó nik'agbako.

🏾K* - Kukuru abi giga -
ìsorò ko ni jẹ tìrẹ.

🏾L* - Loniloni wa r'aanu
gba.

🏾M*- Mọnamọna ati àra
Ọlọ́run yóò tu àwọn
ọta rẹ ka.

🏾N* - Naira, Euro, Dollar,
Pound, Yen, Yuan,
gbogbo owo ati ọrọ
kaakiri agbaye pẹlu
ọmọ alalubarika ati
alaafia yóò mu ọ
l'ọrẹ, wọn o si fi ile
re ṣe ibugbe.

🏾O* - Ojurere ati aanu yio
ma tọ ọ lẹ́yìn ni ọjọ
aye rẹ̀ gbogbo.

🏾Ọ* - Ọjọ́ ọ̀la rẹ a dara.

🏾P* - Panpẹ aye ò ni mu ọ
t'ọmọtọmọ.

🏾R* - Rere ni agogo aye rẹ
yió ma lu n'igba
gbogbo.

🏾S* - Suuru pẹlu ìtẹ́lọ́rùn
ninu ọrọ at'alaafia
yi o ba ọ́ kalẹ.

🏾Ṣ* - Ṣugbọ́n ati àbáwọn
aye rẹ ti poora loni.

🏾T* - T'ọmọtọmọ, t'ẹbitẹbi,
t'iletile o ni d'ero ẹyin.

🏾U* A kii wátí U ti l'ede
Ekiti Ujẹ̀ṣà; a o ni fi ọ̀
ṣàwátí laarin awọn
ọniyan (eniyan).
Ulọsiwaju (ilọsiwaju),
ure (ire), ati ubukun
(ibunkun) yio jẹ́ tìrẹ.

🏾W* - Wa ri ba ti ṣe, wa
r'ọna gbe gba.

🏾Y* - Yara ibukun, ire, ati
ayo ailopin loo ma
ba ọ gbe titi ọjọ aye
rẹ......

_🏾AMIN, L'AṢẸ EDUMARE.*_

_*IRE O!*_

_🏳Ìwọ naa fi ranṣẹ si
awon olólùfẹ́ rẹ. Bẹe ni, o
le fi ránṣẹ si emi naa ti
moba wa lara àwọn
olólùfẹ́ rẹ._
--
Share:
Copyright © Naija Google Blogger | Powered by Blogger Design by ronangelo | Blogger Theme by NewBloggerThemes.com